Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló ti rẹ̀ sára àmọ́ inú wa dùn pé a gbòmìnira – Àwọn tó gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ Boko Haram

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/Facebook
Awọn ẹbi awọn ọmọde ti wọn gba itusilẹ kuro ni ahamọ awọn ajinigbe lopin ọsẹ ti fi idunnu wọn lori bi awọn ọmọ naa ṣe gba itusilẹ.
Ko din ni awọn eeyan 360 to fi mọ ọmọde atawọn obinrin tawọn Boko Haram ji gbe ni ilu Ngoshe ti wọn gba itusilẹ lẹyin ti wọn lo ọpọ oṣu ni ahamọ aɛọn ajinigbe naa.
Ọkan lara awọn ẹbi awọn eeyan naa, Musa Hamman Dada, ẹni ti wọn pa eeyan rẹ lasiko ikọlu si ilu Ngoshe, ti awọn ẹbi rẹ to wa ninu awọn ti wọn tu silẹ to ọgbọn sọ fun BBC pe wọn ti ko awọn eeyan naa lọ sile awọn eeyan ti ko nile lori mọ.
O ni ile naa wa ni ilu Pulka, ibi to to iwọn kilomita si ilu ti ijinigbe naa ti waye, to si sọ pe inu oun dun gidi si bi awọn eeyan naa ṣe gba itusilẹ amọ to ni awọn eeyan naa ni oun ti wọn ti la kọja ni ahamọ ajinigbe kọja ki wọn fi wọn silẹ lati maa dagbe lọ.
Hamman Dada to jẹ olori ilu ni agbegbe naa ni bi o tilẹ jẹ pe itusilẹ awọn eeyan naa dun mọ awọn, o ni ko tọ ki awọn eeyan naa kan pada si aarin ilu leyin ti wọn ti wa ni ahamọ ajinigbe fun oṣu mẹta.
Ọkan lara awọn to gba itusilẹ naa, Aisha Mohammed sọ fun BBC pe ọpọ awọn ọmọde lo padanu ẹmi wọn si ahamọ awọn ajinigbe naa nigba ti awọn wa nigbekun wọn.
Aisha ni ọpọ ọmọ to n mu ọyan lọwọ lo jade laye nitori awọn iya wọn ko ri ounjẹ gidi jẹ lati fun wwọn ni omi ọyan to to.
O ni inu oun dun lati pada sile amọ to ni iriri oun ni ahamọ awọn ikọ Boko Haram kii ṣe ohun ti oun le gbagbe laelae.
"Inu igbo la n sun, ọpọ wa lo ko aarun, ti a si n ṣaarẹ gidi bayii. Ko si ounjẹ ajẹkanu. Awọn to ji wa gbe maa fun wa lounjẹ tutu nigba mii lati se e funra wa ṣugbọn ounjẹ naa kii to nnkankan.
"Titi di asiko yii, awọn ọmọde kan wa to rẹ wọn gidi, awọn mii ṣi wa ni ahamọ, inu mi dun pe mo wa lara awọn ti wọn tu silẹ."
Ẹlomii, ti oun naa wa lara awọn to n ṣe itọju awọn ti wọn tu silẹ naa, Musa Jidda sọ fun BBC pe ọpọ awọn ti wọn gba itusilẹ naa lo nilo ounjẹ gidi, ti wọn si nilo ayẹwo to peye fun bii ọsẹ meji si ọsẹ mẹta ki wọn to le ni okun ninu.
O ni lara awọn eeyan naa ni awọn ti fi ranṣẹ si ilu Maiduguri lati lọ gba itọju to peye nitori wọn ko le ṣetọju wọn ni ilu naa paapaa awọn ọmọde.
Nigba to n sọrọ lori itusilẹ awọn eeyan naa, gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum gboriyin fun ileeṣẹ Ologun atawọn ẹṣọ aabo mii fun bi wọn ṣe gba itusilẹ awọn eeyan naa.
Gomina Zulum ni itusilẹ awọn eeyan naa ṣafihan ifarajin awọn ọmọ ogun nidii gbigbogun ti iwa igbeṣumọmi ni ẹkun ila oorun ariwa Naijiria.
O ni bi wọn ṣe gba itusilẹ awọn eeyan to ti wa ni ahamọ awọn agbeṣumọmi naa ti da ireti awọn eeyan ilu naa pada, to si ṣafihan ifarajin ileeṣẹ Ologun, ijọba Naijiria ati ijọba ipinlẹ Borno lori mimu aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ni okunkundun.
Ṣé lóòótọ́ ni Boko Haram yọ̀ǹda èèyàn 416 tí wọ́n jí gbé ní Borno? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, BOSYA/PUNCH
Iroyin kan to gbode bayii ni pe ko din ni eeyan mẹrindin ni ookolenirinwo (416) ti awon ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ti tu silẹ bayii lẹyin ti wọn ji wọn gbe niluu Ngoshe, ijọba ibilẹ Gwoza, ipinlẹ Borno loṣu Kẹta ọdun 2026 yii.
Ẹka iroyin Punch to kede iroyin naa lọjọ Aiku, ọjọ keje oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii, sọ pe aarẹ ẹgbẹ awọn ọdọ kan ni Borno, 'Borno South Youth Alliance', (BOSYA) Samaila Kaigama,lo fidi ẹ mulẹ pe ana ode yii ti i ṣe ọjọ Satide ni wọn fi awọn eeyan naa silẹ.
Ọpọ obinrin ati awọn ọmọde ni wọn pe awọn ti wọn ni Boko Haram tu silẹ naa.
Alaye BOSYA
Aarẹ ẹgbẹ BOSYA, Samaila Kaigama, ṣalaye fun Punch pe ẹgbẹ yii lo jẹ alarena laaarin ikọ agbesunmọmi naa ati awọn ti wọn ji gbe.
Wọn fi kun un pe BOSYA lo n ba awọn akọroyin sọrọ lati ọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin ọdun yii nipa bi ohun gbogbo ṣe n lọ laaarin awọn ajinigbe atawọn to wa nigbekun wọn.
Kaigama sọ fun Punch pe:
"BOSYA ti gba awọn obinrin atawọn ọmọde Ngoshe ti iye wọn jẹ 416. Wọn fi wọn silẹ lọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa.
"Inu wa dun, a si dupẹ pe lati ara igbiyanju wa, ẹkun asunndakẹ wa ati ajọsọ ọrọ fun igba pipẹ, ati ri esi bayii."
O rọ ijọba apapọ Naijiria ati ijọba ipinlẹ Borno atawọn ẹka to ba yẹ gbogbo, lati ṣayẹwo finnifinni fawọn ti wọn ṣẹṣẹ ti ibuba ajinigbe de yii.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrin oṣu Kẹta ọdun 2026 yii ni iroyin jade, pe awọn agbebọn yabo ileeṣẹ awọn ologun Naijiria to wa niluu Ngoshe, nipinlẹ Borno.
Wọn dana sun awọn ọkọ tawọn ologun naa n lo, ṣi ọpọ ologun nidii kuro ni aaye wọn, bẹẹ ni wọn si pa ọpọ eeyan, wọn gbe pupọ wọgbo lọ.
Afikun:Ileeṣẹ ọlọpaa tabi ẹka kankan ko ti i fi atẹjade sita lori ọrọ yii nigba ti a pari akojọpọ iroyin yii.


























