BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Inú gbogbo èèyàn ìpínlẹ̀ Osun ló dún sí ìdájọ́ tó fààyè gba Accord láti díje, Adeleke ní wọ́n ń fẹ́ - Ìjọba Osun
Agbẹnusọ fun Gomina Ademola Adeleke, Olawale Rasheed to ba BBC News Yoruba sọrọ lori idajọ naa sọ pe ki i ṣe gomina nikan ni idajọ ọhun dun mọ, bi ko ṣe gbogbo ọmọ ipinlẹ Osun pata.
Inú ìbànújẹ ọkàn ni mo wà torí àwọn ọmọdé wà ninu awọn èèyàn tawon janduku agbébọn ji gbe, bẹẹ, o ti le ni oṣu kan bayii- Makinde
Makinde sọrọ yii lasiko ti alẹ́nulọ́rọ̀ ori ayélujára, Very Dark Man, at'awọn ọdọ mii n ṣèwọ́de niluu Ibadan lati pe fún ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wọn ji gbe ọhun.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 0,55
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Fídíò, Ìjọba Aiyedatiwa fẹ́ lé wa kúrò ní Agọ Ireti, ó tún kọ̀ láti fún wa ní owó oṣù wa – Àwọn olùgbé Agọ Ireti, Duration 3,29
Lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn olugbe Agọ Ireti naa ṣe iwọde niluu Akure lẹyin ti wọn ni awọn gbọ pe ijọba ipinlẹ ọhun fẹ le awọn kuro nibẹ lọ si agbegbe mii.
Àdó olóró agbésùnmọ̀mí ṣekúpa ọlọ́pàá mẹ́ta
Orukọ awọn agbofinro to padanu ẹmi naa bi ijọba ipinlẹ Zamfara ṣe kede ni: Abdulrazak Musa Hassan, Auwal Ahmad ati Murtala Musa.
Wo bí Ọlọ́pàá ṣe ká ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbọn, ọta ìbọn, aṣọ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord àti ọkọ̀ lákàtà afurasí adigunjalè, Surii Ilupeju ní Ibadan
Ibọn marun un, ọta ibọn mọkanlelọgbọn, ọkọ bọọsi mẹfa pẹlu ọkọ mẹrin miran atawọn ọkada wa lara ohun ti wọ̀n ba ni ikawọ afurasi naa.
Hijrah: Kí ni pàtàkì ọdún tuntun yìí fún àwọn mùsùlùmí?
Iyatọ to wa laarin ọdun musulumi ati ọdun yooku ni pe wọn ko kii ṣe e papọ pẹlu awọn yooku ati pe orukọ wọn yatọ.
Kí ló dé tí ẹnu ń kun Bàbá Ijesha lẹ́yìn tó kéde ọmọ tuntun?
Ninu fidio kan ti Baba Ijesha fi soju opo Instagram rẹ lo ti kede iroyin pe oun ati iyawo oun, Ceoluminee ti bi ọmọkunrin to pe orukọ rẹ ni King Kagar.
Ṣé lóòótọ́ ni Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Osun ń hùwà kò kàn mí sí rògbòdìyàn òṣèlú àti ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ náà? Ohun tí a mọ̀ rèé
Awọn ọdọ to ṣe iwọde l'Osogbo sọ pe bi Ọga Ọlọpaa ipinlẹ Osun, Ibrahim Gotan, ṣe dakẹ si gbogbo rogbodiyan n to ṣẹlẹ ni ipinlẹ Osun lasiko yii ku diẹ kaato.
Iléeṣẹ́ ọmogun dóòlà ìyàwó ọ̀gágunfẹ̀yìntì tó kú sí àkàtà àwọn jàndùkú agbébọn lẹ́yìn tí wọ́n sin ọkọ rẹ̀
Alukoro fun ileeṣẹ ọmogun Naijiria, Ọgagun Samaila Uba, lo fọrọ yii lede lalẹ ọjọ Aje ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹfa yii.
Ṣé lóòótọ́ làwọn agbésùnmọ̀mí Lukarawa láti Apá Àríwá ti wọ inú igbó lọ l'Ogbomoso? Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo ti sọ̀rọ̀
Ileeṣẹ ọlọpaa Oyo sọ ninu atẹjade kan to fi sita loju opo X rẹ wi pe fidio naa ati ohun to wa nibẹ ko lẹsẹ nlẹ rara.
Kí ló pa Oriyomi pọ̀ pẹ̀lú Surii Ilupeju, afurasí adigunjalè tí ọlọ́pàá ń wá? Ohun tí a mọ̀ rèé
Oriyomi ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe awọn ti wọn loun ni ibaṣepọ pẹlu Surajudeed fẹ ṣakoba fun ipolongo ibo oun ni.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Kò sí ogun mọ́, kò sí ọ̀tẹ̀ mọ́! Amẹ́ríkà àti Iran fẹnukò láti fòpin sí ogun àárín wọn
Olootu ijọba orilẹede Pakistan, Shehbaz Sharif, to jẹ alarena laarin orilẹede mejeji lo fi ọrọ naa lede lalẹ ọjọ Aiku.
Ọmọsẹ́ gbẹ̀mí ọ̀gá rẹ̀ ní Kwara, ó tún ń bèrè ₦2m lọ́wọ́ ẹbí olóògbé
Ọga agba ajọ NSCDC, Abbas Nda Mohammed lo fi ọrọ naa lede lọjọ Aiku, ọjọ kẹrinla, osu Kẹfa, ọdun 2026 ti a wa yii ni olu ileesẹ ajọ naa lẹyin iwadii lori bi oloogbe ọhun ṣe dede dawati.
Àwọn afurasí tó lé ní 400 yóò fojú balé ẹjọ́ lónìí lórí ìgbéṣùmọ̀mí
Igbẹjọ yii lo n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti irufẹ igbẹjọ bẹẹ waye ninu oṣu Kẹrin ọdun yii nibi ti ijọba ti wọ awọn afurasi to le ni ẹẹdẹgbẹta lọ sile ẹjọ lori igbeṣumọmi ti ile ẹjọ si dajọ fun awọn to le ni 386 ninu wọn.
Àjọ CAN kéde ọjọ́ òní gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ 'Àìkú Dúdú' láti dárò àwọn ọmọ Naijiria tó ń jìyà ètò ààbò tó mẹ́hẹ
CAN kede ọrọ naa ninu iṣẹ ti Aarẹ wọn, Archbishop Daniel Okoh, ran si gbogbo Kristẹni lonii ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa ọdun 2026.
Ìtàn Mánigbàgbé: Ìdí tí Ọba alayé nílẹ̀ Yorùbá kìí ṣe dúró níbi tí wọn ti ń pa èèyàn tàbí fojú rí òkú
BBC News Yorùbá wọnú ìtàn lọ nípa ìdí tí Ọba alayé nílẹ̀ Yorùbá kìí ṣe dúró níbi tí wọn ti ń pa èèyàn tàbí fojú rí òkú.
Agbébọn kọlu Owo ní ìpínlẹ̀ Ondo, jí baálẹ̀ gbé lọ ní ààfin
Awọn olugbe ilu naa ṣalaye pe awọn agbebọn mẹfa lo wọ aafin naa, ti wọn si sọsẹ yi lai si ẹni to yẹ wọn lọwọ wo.
Switzerland fẹ́ ṣòfin tí kò ní jẹ́ kí gbogbo èèyàn orílẹ̀èdè náà kọjá mílíọ́nù mẹ́wàá
Njẹ o ṣeeṣe ki orilẹede kan ma jẹ ki iye eeyan to wa nilẹ rẹ kọja iye ti wọn n fẹ? Ibeere ti orilẹede Switzerland yoo maa dahun lonii ọjọ Aiku ree nibi ipade apero kan.
Wo ìdílé mẹ́wàá tí wọ́n lówó jùlọ káàkiri àgbáyé
Lara awọn nnkan ti wọn ti ṣe to sọ wọn di ọlọrọ ni ile tabi ilẹ tita, aṣọ tita, ounjẹ tita ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Makinde sọ̀rọ̀ lórí ibi táwọn agbébọn kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso pamọ́ sí
Gomina ipinlẹ Oyo sọ ninu atẹjade kan to fi sita fawọn akọroyin pe ninu igbo ijọba Old Oyo National Park lawọn ajinigbe naa wa pẹlu awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso.
Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Kola Oyewo, àgbà òṣèré tíátà Yoruba tó jáde láyé
Àwọn gbajúmọ̀ òṣèré bíi Kunle Afod ati Yomi Ọlọrunlaiye ni wọ́n ti ń daro ipapoda àgbà òṣèré náà.
Ọdún mẹ́sàn án rèé tí mo ti ń gbé pẹ̀lú àrun kògbóògùn, HIV kìí ṣe ìdájọ́ ikú – Chika Wonder
Ọrọ ti Chika Ekezie ti ọpọ mọ si Chika Wonder sọ ree lasiko to ba BBC sọrọ lori irinajo rẹ pẹlu arun naa.
Iléeṣẹ́ ológun Naijiria kéde àwọn agbéṣùmọ̀mí méjì tó juwọ́ sílẹ̀ fún ìjọba
Ileeṣẹ Ologun to fi iroyin naa lede lori ayelujara kede orukọ awọn agbeṣumọmi ti wọn juwọ lẹ naa bii Ismail Mohammed ati Abu Umar.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ìtàgé tó jìn mọ́ Gómìnà Adeleke àtàwọn ikọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀ níbi ìpolongo ìbò l'Osun, ohun tí a mọ̀ rèé
Ilu Ijebu-Jesa, nijọba ibilẹ Oriade ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara nawọ́ gán afurasí ajínigbé mẹ́sàn-án, àkàrà bá tú sépo
Atẹjade kan ti agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa Kwara Adetoun Ejire-Adeyemi fi lede ṣalaye pe yatọ si awọn afurasi ajinigbe naa, ọwọ ọlọpaa tun tẹ ọkunrin kan ti igbagbọ wa pe o n ṣe agbodegba fun awọn ajinigbe ni ijọba ibilẹ Batuten.
Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó sọ ''June 12'' di àyájọ́ ìjọba tiwantiwa àti mánigbàgbé yíká Nàìjíríà títí di òní
Lónìí àyájọ́ June 12, BBC News Yorùbá wọ inú ìtàn lọ láti ṣàlàyé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé tí June 12 ṣe di ọjọ́ ìjọba alágbádá àti mánigbàgbé nínú ìtàn Nàíjíríà.
Bí ilé aṣojú-ṣòfin ṣe fòńtẹ̀ lu àbá ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀, wo ìlànà ìṣẹ́ wọn, àǹfààní àti ewu rẹ̀
Lasiko ti wọn dibo lori aba naa lati gba a wọle, aṣofin 288 lo faramọ ọn, nigba ti awọn mẹrin sọ pe awọn ko fẹ idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ.
Ìfẹ̀hónúhàn wáyé káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ lórí ààbò tó mẹ́hẹ, bèèrè fífi òpin sí ìjínigbé
Latari bi nnkan ko ṣe fararọ kaakiri lorilẹede Naijiria bayii, paapaa lẹka aabo ati ọrọ aje, ọpọ araalu ni inu wọn ko dun.
Àwọn agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ nígboro South Africa, èèyàn méjìlá kú, mẹ́sàn-án farapa
Gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe fi han, orilẹede South Africa wa lara awọn ilu ti wọn ti n pa eeyan ju lagbaaye.
Ẹgbẹ́ City Boys tó ń ṣàtìlẹyìn fún Tinubu l‘Oyo ṣàbẹ̀wó sí Esinele, gbé ohun èlò ìwòsàn kalẹ̀, àmọ́ ẹbí Tíṣà tí agbébọn pa kọ àpò ìrẹsì àti owó Ìyálọ́jà, tíí ṣe ọmọ ààrẹ
Nigba to n sọrọ lasiko abẹwo ọhun, Onireti fi ireti han pe wọn maa ṣawari awọn akẹkọọ atawọn olukọ tawọn ajinigbe naa ji gbe laipẹ, bi o ṣe ni pe ijọba n sapa wọn lati gba itusilẹ awọn eeyan naa.








































































